Video Emi Lo Kan » Qdot Lyrics | Musica Afro

Ver Video y Lyrics con la música del Genero Afro más popular de Qdot y otros artistas en línea. Disfruta de las mejores canciones de 2025 en LetrasFM de música en línea. ¡Encuentra tu canción favorita y escúchala en cualquier momento y en cualquier lugar!

Video Emi Lo Kan » Qdot Lyrics

Qdot - Emi Lo Kan Lyrics


Ọmọ ọmọ Mọriamọ
(2T up on the beat)
Qdot lórúkọ mi
(Kúró ńbẹ̀ yẹn náà)

Ó ṣe kìn-ín-ní lulẹ̀
Ó ṣe kejì lulẹ̀
Ó ṣe kẹta lulẹ̀
Ẹ dákún, ẹ má jẹ́ kó ṣe kẹrin
(Èmi ló kàn)

Ẹ gbé kiní yìí wá (Èmi ló kàn)
Kiní yìí, kiní mi (Èmi ló kàn)
Áńgẹ́lì tó ń pín ire (Èmi ló kàn)
Pín ire kàn mí (Èmi ló kàn)
Mo gbọ́dọ̀ lówó (Èmi ló kàn)
Ọmọ Ọlọ́run ò gbọ́dọ̀ ṣẹ́ṣó (Èmi ló kàn)
Ire owó (Èmi ló kàn)
Ire ọmọ (Èmi ló kàn)
Àlùbáríkà (Èmi ló kàn)
London wọnú Amẹ́ríkà (Èmi ló kàn)
Dubai wọ Kánádà (Èmi ló kàn)
Báyìí kọ́ là ń ṣe kọ́ ọ̀rọ̀ mi (Èmi ló kàn)
Ìran mẹ́ta, ò gbọ́dọ̀ di òṣì (Èmi ló kàn)
Kórí mi, dorí owó (Èmi ló kàn)
Kórí mi, dorí àpèsìn (Èmi ló kàn)
All I need is blessing (Èmi ló kàn)

Ó ṣe kìn-ín-ní lulẹ̀
Ó ṣe kejì lulẹ̀
Ó ṣe kẹta lulẹ̀
Ẹ dákún, ẹ má jẹ́ kó ṣe kẹrin
(Èmi ló kàn)

Ọdún yìí, ọdún mi ni (Èmi ló kàn)
Orí mi má já mi kúnlẹ̀ (Èmi ló kàn)
Ọlọ́run ọ̀nà ìwà mímọ́ (Èmi ló kàn)
Ọlọ́run Asakiatu (Èmi ló kàn)
Màlékà wa ló dà? (Èmi ló kàn)
Káyé má bí mi pé: ọlọ́run mi dà? (Èmi ló kàn)
Àwọn ẹlẹ́nu ṣọ-ṣọ-ṣọ (Èmi ló kàn)
Àwọn ẹlẹ́nu ṣo-ṣo-ṣo (Èmi ló kàn)
Wọ́n dẹ̀ máa sọ ìsọkúsọ (Èmi ló kàn)
Wo ọlá Bíbélì rẹ (Èmi ló kàn)
Wo ọlá Kùránì rẹ (Èmi ló kàn)
Wo ọlá kiní àwọn baba mi kàn (Èmi ló kàn)
Tó dún woroworo (Èmi ló kàn)
Baba má jẹ́ n pòfo (Èmi ló kàn)
Baba ṣe ìyanu láyé mi (Èmi ló kàn)
Kí n yẹ fi orí olórí tọ́ọ́rọ́ (Èmi ló kàn)

Ó ṣe kìn-ín-ní lulẹ̀
Ó ṣe kejì lulẹ̀
Ó ṣe kẹta lulẹ̀
Ẹ dákún, ẹ má jẹ́ kó ṣe kẹrin
(Èmi ló kàn)

Ìgbà mi ló dé (Èmi ló kàn)
Ọmọ Mọriamọ fẹ́ gba adé (Èmi ló kàn)
Ẹ sọ fún Sunny al'Ádé (Èmi ló kàn)
Ọ̀rọ̀ tẹ́ bá sọ fún Ṣàngó (Èmi ló kàn)
Ṣàngó máa sọ fún Ọya (Èmi ló kàn)
Ẹ sọ fún Dangote pé kó sọ fún Ọkọ́ya (Èmi ló kàn)
Èmi náà fẹ́ ṣàánú ènìyàn (Èmi ló kàn)
Bí ti Dende n'Ílaró (Èmi ló kàn)
MC ń fówó Yẹ́misí (Èmi ló kàn)
Mo mọ Riliwan Cooler (Èmi ló kàn)
Èèyàn Paso (Èmi ló kàn)
Alágbé tó bá lá ju olówó (Èmi ló kàn)
Arówólò lòun ta mọ́tò (Èmi ló kàn)
Doctor Brown (Èmi ló kàn)
Lánre Typical (Èmi ló kàn)
Tí n bá ní: Un-un un-un (Èmi ló kàn)
Tí n bá ní: ẹn-ẹn ẹn-ẹn (Èmi ló kàn)
Wò, èmi lòye (Èmi ló kàn)
Mi ò fi gbogbo ẹnu sọ̀rọ̀ (Èmi ló kàn)
Kàn má tì mí mọ́ kọ̀rọ̀ (Èmi ló kàn)
A mọ èèyàn l'Ábùújá (Èmi ló kàn)
2T máa lùlù ó máa dùn (Èmi ló kàn)
Tó bá ti dún, ó dẹ̀ máa dùn (Èmi ló kàn)

Ó ṣe kìn-ín-ní lulẹ̀
Ó ṣe kejì lulẹ̀
Ó ṣe kẹta lulẹ̀
Ẹ dákún, ẹ má jẹ́ kó ṣe kẹrin
(Èmi ló kàn)

2T on the mix

Emi Lo Kan » Qdot Letras !!!
Esta web no aloja ningun archivo mp3©LetrasFM.Info 2025 Colombia - Chile - Argentina - Mexico. All Rights Reserved.

Musica Online, Escuchar musica online , Musica En Linea, Musica en linea gratis, Escuchar Musica Gratis, Musica Online 2025, Escuchar Musica

Musica 2025, Musica 2025 Online, Escuchar Musica Gratis 2025, Musica 2025 Gratis, Escuchas, Musica de Moda.